62. Ó jẹ́ kí á fi idà pa àwọn eniyan rẹ̀;ó sì bínú gidigidi sí àwọn eniyan ìní rẹ̀.
63. Iná run àwọn ọdọmọkunrin wọn;àwọn ọdọmọbinrin wọn kò sì rójú kọrin igbeyawo.
64. Àwọn alufaa kú ikú ogun;àwọn opó wọn kò sì rójú sọkún.
65. Lẹ́yìn náà, OLUWA dìde bí ẹni tají lójú oorun,bí ọkunrin alágbára tí ó mu ọtí yó tí ó ń kígbe.
66. Ó lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ sẹ́yìn;ó dójú tì wọ́n títí ayé.
67. Ó kọ àgọ́ àwọn ọmọ Josẹfu sílẹ̀;kò sì yan ẹ̀yà Efuraimu;
68. ṣugbọn ó yan ẹ̀yà Juda,ó sì yan òkè Sioni tí ó fẹ́ràn.
69. Níbẹ̀ ni ó kọ́ ibi mímọ́ rẹ̀ tí ó ga bí ọ̀run sí,ó sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ bí ayé títí lae.
70. Ó yan Dafidi iranṣẹ rẹ̀;ó sì mú un láti inú agbo ẹran.
71. Ó mú un níbi tí ó ti ń tọ́jú àwọn aguntantí ó lọ́mọ lẹ́yìn,kí ó lè máa tọ́jú àwọn ọmọ Jakọbu, eniyan rẹ̀,àní àwọn ọmọ Israẹli, eniyan ìní rẹ̀.