Orin Dafidi 78:52-66 BIBELI MIMỌ (BM)

52. Lẹ́yìn náà, ó kó àwọn eniyan rẹ̀ jáde bí agbo ẹranó sì dà wọ́n láàrin aṣálẹ̀ bí agbo aguntan.

53. Ó dà wọ́n lọ láìléwu, ẹ̀rù kò bà wọ́n;òkun sì bo àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀.

54. Ó kó wọn wá sí ilẹ̀ mímọ́ rẹ̀,sí orí òkè tí ó ti fi agbára rẹ̀ gbà.

55. Ó lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde kí wọn ó tó dé ibẹ̀;ó pín ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn bí ohun ìní;ó sì fi àwọn ọmọ Israẹli jókòó ninu àgọ́ wọn.

56. Sibẹ, wọ́n dán Ọ̀gá Ògo wò, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí i;wọn kò tẹ̀lé ìlànà rẹ̀.

57. Wọ́n yipada, wọ́n sì hu ìwà ọ̀dàlẹ̀bíi ti àwọn baba ńlá wọn;wọn kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, wọ́n dàbí ọfà tí ó tẹ̀.

58. Wọ́n fi ojúbọ àwọn oriṣa wọn bí i ninu;wọ́n sì fi ère wọn mú un jowú.

59. Nígbà tí Ọlọrun gbọ́, inú bí i gidigidi;ó sì kọ Israẹli sílẹ̀ patapata.

60. Ó kọ ibùgbé rẹ̀ ní Ṣilo sílẹ̀,àní, àgọ́ rẹ̀ láàrin ọmọ eniyan.

61. Ó jẹ́ kí á gbé àmì agbára rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn;ó sì fi ògo rẹ̀ lé ọ̀tá lọ́wọ́.

62. Ó jẹ́ kí á fi idà pa àwọn eniyan rẹ̀;ó sì bínú gidigidi sí àwọn eniyan ìní rẹ̀.

63. Iná run àwọn ọdọmọkunrin wọn;àwọn ọdọmọbinrin wọn kò sì rójú kọrin igbeyawo.

64. Àwọn alufaa kú ikú ogun;àwọn opó wọn kò sì rójú sọkún.

65. Lẹ́yìn náà, OLUWA dìde bí ẹni tají lójú oorun,bí ọkunrin alágbára tí ó mu ọtí yó tí ó ń kígbe.

66. Ó lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ sẹ́yìn;ó dójú tì wọ́n títí ayé.

Orin Dafidi 78