38. Sibẹ, nítorí pé aláàánú ni, ó dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n,kò sì pa wọ́n run;ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó dáwọ́ ibinu rẹ̀ dúró,tí kò sì fi gbogbo ara bínú sí wọn.
39. Ó ranti pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n,afẹ́fẹ́ lásán tí ń fẹ́ kọjá lọ, tí kò sì ní pada mọ́.
40. Ìgbà mélòó ni wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i ninu ijù,tí wọ́n sì bà á lọ́kàn jẹ́ ninu aṣálẹ̀!
41. Wọ́n dán an wò léraléra,wọ́n sì mú Ẹni Mímọ́ Israẹli bínú.
42. Wọn kò ranti agbára rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ranti ọjọ́ tí ó rà wọ́n pada lọ́wọ́ ọ̀tá;
43. nígbà tí ó ṣe iṣẹ́ abàmì ní ilẹ̀ Ijipti,tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní oko Soani.
44. Ó sọ omi odò wọn di ẹ̀jẹ̀,tí wọn kò fi lè mu omi wọn.
45. Ó rán ọ̀wọ́ eṣinṣin sí wọn tí ó jẹ wọ́n,ati ọ̀pọ̀lọ́ tí ó pa wọ́n run.
46. Ó mú kí kòkòrò jẹ èso ilẹ̀ wọn;eṣú sì jẹ ohun ọ̀gbìn wọn.
47. Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́;ó sì fi òjò dídì run igi Sikamore wọn.
48. Ó fi yìnyín pa mààlúù wọn;ó sì sán ààrá pa agbo aguntan wọn.
49. Ó tú ibinu gbígbóná rẹ̀ lé wọn lórí:ìrúnú, ìkannú, ati ìpọ́njú,wọ́n dàbí ikọ̀ ìparun.
50. Ó fi àyè gba ibinu rẹ̀;kò dá ẹ̀mí wọn sí,ó sì fi àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n.
51. O kọlu gbogbo àkọ́bí wọn ní ilẹ̀ Ijipti,àní, gbogbo àrẹ̀mọ ninu àgọ́ àwọn ọmọ Hamu.
52. Lẹ́yìn náà, ó kó àwọn eniyan rẹ̀ jáde bí agbo ẹranó sì dà wọ́n láàrin aṣálẹ̀ bí agbo aguntan.
53. Ó dà wọ́n lọ láìléwu, ẹ̀rù kò bà wọ́n;òkun sì bo àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀.
54. Ó kó wọn wá sí ilẹ̀ mímọ́ rẹ̀,sí orí òkè tí ó ti fi agbára rẹ̀ gbà.
55. Ó lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde kí wọn ó tó dé ibẹ̀;ó pín ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn bí ohun ìní;ó sì fi àwọn ọmọ Israẹli jókòó ninu àgọ́ wọn.
56. Sibẹ, wọ́n dán Ọ̀gá Ògo wò, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí i;wọn kò tẹ̀lé ìlànà rẹ̀.