Orin Dafidi 77:5-20 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Mo ranti ìgbà àtijọ́,mo ranti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn.

6. Mo ronú jinlẹ̀ lóru,mo ṣe àṣàrò, mo yẹ ọkàn mi wò.

7. Ṣé Ọlọrun yóo kọ̀ wá sílẹ̀ títí lae ni;àbí inú rẹ̀ kò tún ní dùn sí wa mọ́?

8. Ṣé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ti pin títí lae ni;àbí ìlérí rẹ̀ ti dópin patapata?

9. Ṣé Ọlọrun ti gbàgbé láti máa ṣoore ni;àbí ó ti fi ibinu pa ojú àánú rẹ̀ dé?

10. Nígbà náà ni mo wí pé, “Ohun tí ó bà mí lọ́kàn jẹ́ ni péỌ̀gá Ògo kò jẹ́wọ́ agbára mọ́.”

11. N óo ranti àwọn iṣẹ́ OLUWA,àní, n óo ranti àwọn iṣẹ́ ìyanu ìgbàanì.

12. N óo máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ;n óo sì máa ronú lórí àwọn iṣẹ́ ribiribi tí o ṣe.

13. Ọlọrun, mímọ́ ni ọ̀nà rẹ;oriṣa wo ni ó tó Ọlọrun wa?

14. Ìwọ ni Ọlọrun tí ń ṣe ohun ìyanu;o ti fi agbára rẹ hàn láàrin àwọn eniyan.

15. O ti fi agbára rẹ gba àwọn eniyan rẹ là;àní, àwọn ọmọ Jakọbu ati Josẹfu.

16. Nígbà tí omi òkun rí ọ, Ọlọrun,àní, nígbà tí omi òkun fi ojú kàn ọ́,ẹ̀rù bà á;ibú omi sì wárìrì.

17. Ìkùukùu da omi òjò sílẹ̀,ojú ọ̀run sán ààrá;mànàmáná ń kọ yẹ̀rì káàkiri.

18. Ààrá ń sán kíkankíkan ní ojú ọ̀run,mànàmáná ń kọ yànràn, gbogbo ayé sì mọ́lẹ̀;ilẹ̀ ayé wárìrì, ó sì mì tìtì.

19. Ọ̀nà rẹ wà lójú omi òkun,ipa ọ̀nà rẹ la omi òkun ńlá já;sibẹ ẹnìkan kò rí ipa ẹsẹ̀ rẹ.

20. O kó àwọn eniyan rẹ jáde bí agbo ẹran,o fi Mose ati Aaroni ṣe olórí wọn.

Orin Dafidi 77