Orin Dafidi 74:18-23 BIBELI MIMỌ (BM)

18. OLUWA, ranti pé àwọn ọ̀tá ń fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́;àwọn òmùgọ̀ eniyan sì ń fi orúkọ rẹ ṣe ẹlẹ́yà.

19. Má fi ẹ̀mí àwa àdàbà rẹ lé àwọn ẹranko lọ́wọ́;má sì gbàgbé àwa eniyan rẹ tí ìyà ń jẹ títí lae.

20. Ranti majẹmu rẹ;nítorí pé gbogbo kọ̀rọ̀ ilẹ̀ wa kún fún ìwà ipá.

21. Má jẹ́ kí ojú ti àwọn tí à ń pọ́n lójú;jẹ́ kí àwọn tí ìyà ń jẹ ati àwọn aláìní máa yin orúkọ rẹ.

22. Dìde Ọlọrun, gbèjà ara rẹ;ranti bí àwọn òmùgọ̀ eniyan tí ń fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru.

23. Má gbàgbé ariwo àwọn ọ̀tá rẹ;àní, igbe àwọn tí ó gbógun tì ọ́, tí wọn ń ké láìdá ẹnu dúró.

Orin Dafidi 74