1. OLUWA, ìwọ ni mo sá di;má jẹ́ kí ojú ó tì mí laelae!
2. Gbà mí, kí o sì yọ mí nítorí òdodo rẹ;tẹ́tí sí mi kí o sì gbà mí là!
3. Máa ṣe àpáta ààbò fún mi,jẹ́ odi alágbára fún mi kí o sì gbà mí,nítorí ìwọ ni ààbò ati odi mi.
4. Ọlọrun mi, gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú,àwọn alaiṣootọ ati ìkà.
5. Nítorí ìwọ OLUWA, ni ìrètí mi,OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé láti ìgbà èwe mi.