21. Iwọ ni wọ́n sọ di oúnjẹ fún mi,nígbà tí òùngbẹ sì ń gbẹ mí,ọtí kíkan ni wọ́n fún mi mu.
22. Jẹ́ kí tabili oúnjẹ tí wọ́n tẹ́ fún arawọn di ẹ̀bìtì fún wọn;kí àsè ẹbọ wọn sì di tàkúté.
23. Jẹ́ kí ojú wọn ṣú,kí wọn má lè ríran;kí gbogbo ara wọn sì máa gbọ̀n rìrì.
24. Rọ òjò ibinu rẹ lé wọn lórí,kí o sì jẹ́ kí wọ́n rí gbígbóná ibinu rẹ.
25. Kí ibùdó wọn ó di ahoro,kí ẹnikẹ́ni má sì gbé inú àgọ́ wọn.
26. Nítorí ẹni tí o ti kọlù ni wọ́n tún gbógun tì;ẹni tí o ti ṣá lọ́gbẹ́ ni wọ́n sì tún ń pọ́n lójú.
27. Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn;má sì jẹ́ kí wọ́n rí ìdáláre lọ́dọ̀ rẹ.
28. Pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò ninu ìwé ìyè;kí á má sì kọ orúkọ wọn mọ́ ti àwọn olódodo.
29. Ojú ń pọ́n mi, mo sì ń jẹ̀rora;Ọlọrun, jẹ́ kí ìgbàlà rẹ gbé mi lékè!