1. Kí Ọlọrun dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ tú ká.Kí àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ sá níwájú rẹ̀.
2. Bí èéfín tií pòórá,bẹ́ẹ̀ ni kí wọn parẹ́;bí ìda tií yọ́ níwájú iná,bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn eniyan burúkú parun níwájú Ọlọrun.
3. Ṣugbọn kí inú àwọn olódodo máa dùn,kí wọn máa yọ̀ níwájú Ọlọrun;kí wọn máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀.
4. Ẹ kọrin sí Ọlọrun, ẹ kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ̀,ẹ pòkìkí ẹni tí ń gun ìkùukùu lẹ́ṣin.OLUWA ni orúkọ rẹ̀;ẹ máa yọ̀ níwájú rẹ̀.
5. Baba àwọn aláìníbaba ati olùgbèjà àwọn opó ni Ọlọrun,ní ibùgbé rẹ̀ mímọ́.
6. Ọlọrun, olùpèsè ibùjókòó fún àlejò tí ó nìkan wà;ẹni tí ó kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n jáde sinu ìdẹ̀ra,ṣugbọn ó sì fi àwọn ọlọ̀tẹ̀ sílẹ̀ ninu ilẹ̀ gbígbẹ.
7. Ọlọrun, nígbà tí ò ń jáde lọ níwájú àwọn eniyan rẹ,nígbà tí ò ń yan la aṣálẹ̀ já,
8. ilẹ̀ mì tìtì, ọ̀run pàápàá rọ òjò,níwájú Ọlọrun, Ọlọrun Sinai,àní, níwájú Ọlọrun Israẹli.
9. Ọlọrun, ọpọlọpọ ni òjò tí o rọ̀ sílẹ̀;o sì mú ilẹ̀ ìní rẹ tí ó ti gbẹ pada bọ̀ sípò.
10. Àwọn eniyan rẹ rí ibùgbé lórí rẹ̀;Ọlọrun, ninu oore ọwọ́ rẹ, o pèsè fún àwọn aláìní.
11. OLUWA fọhùn,ogunlọ́gọ̀ sì ni àwọn tí ó kéde ọ̀rọ̀ rẹ̀.
12. Gbogbo àwọn ọba ni ó sá tàwọn tọmọ ogun wọn;àwọn obinrin tí ó wà nílé,
13. ati àwọn tí ó wà ní ibùjẹ ẹran rí ìkógun pín:fadaka ni wọ́n yọ́ bo apá ère àdàbà;wúrà dídán sì ni wọ́n yọ́ bo ìyẹ́ rẹ̀.
14. Nígbà tí Olodumare tú àwọn ọba ká,ní òkè Salimoni, yìnyín bọ́.
15. Áà! Òkè Baṣani, òkè ńlá;Áà! Òkè Baṣani, òkè olórí pupọ.
16. Ẹ̀yin òkè olórí pupọ,kí ló dé tí ẹ̀ ń fi ìlara wo òkè tí Ọlọrun fẹ́ràn láti máa gbé,ibi tí OLUWA yóo máa gbé títí lae?