1. Gbogbo ayé, ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọrun.
2. Ẹ kọ orin ògo yin orúkọ rẹ̀;ẹ yìn ín, ẹ fògo fún un!
3. Ẹ sọ fún Ọlọrun pé,“Iṣẹ́ rẹ bani lẹ́rù pupọ,agbára rẹ pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́,tí àwọn ọ̀tá rẹ fi ń fi ìbẹ̀rù tẹríba fún ọ.
4. Gbogbo ayé ní ń sìn ọ́;wọ́n ń kọ orin ìyìn fún ọ,wọ́n ń kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.”
5. Ẹ wá wo ohun tí Ọlọrun ṣe,iṣẹ́ tí ó ń ṣe láàrin ọmọ eniyan bani lẹ́rù.
6. Ó sọ òkun di ìyàngbẹ ilẹ̀,àwọn eniyan fi ẹsẹ̀ rìn kọjá láàrin odò.Inú wa dùn níbẹ̀ nítorí ohun tí ó ṣe.
7. Nípa agbára rẹ̀ ó ń jọba títí lae.Ó ń ṣọ́ àwọn orílẹ̀-èdè lójú mejeeji,kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má gbéraga sí i.
8. Ẹ yin Ọlọrun wa, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,ẹ jẹ́ kí á gbọ́ ìró ìyìn rẹ̀;
9. ẹni tí ó dá wa sí tí a fi wà láàyè,tí kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa yẹ̀.
10. Nítorí ìwọ, Ọlọrun, ti dán wa wò;o ti dán wa wò bíi fadaka tí a dà ninu iná.
11. O jẹ́ kí á bọ́ sinu àwọ̀n;o sì di ẹrù wúwo lé wa lórí.
12. O jẹ́ kí àwọn eniyan máa gùn wá lórí mọ́lẹ̀,a ti la iná ati omi kọjá;sibẹsibẹ o mú wa wá sí ibi tí ilẹ̀ ti tẹ́jú.
13. N óo wá sinu ilé rẹ pẹlu ọrẹ ẹbọ sísun;n óo sì san ẹ̀jẹ́ mi fún ọ.
14. Ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́,tí mo sì fi ẹnu mi sọ nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú.