Orin Dafidi 59:14-17 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Ní alaalẹ́ wọn á pada wáwọn á máa hu bí ajá, wọn á sì máa kiri ìlú.

15. Wọn á máa fẹsẹ̀ wọ́lẹ̀, wọn á máa wá oúnjẹ kiri,bí wọn ò bá sì yó wọn á máa kùn.

16. Ṣugbọn èmi ó kọrin ìyìn agbára rẹ;n óo kọrin sókè lówùúrọ̀, nípa ìfẹ́ rẹ tíkì í yẹ̀.Nítorí ìwọ ni o ti jẹ́ odi miìwọ sì ni ààbò mi nígbà ìpọ́njú.

17. Ọlọrun, agbára mi, n óo kọ orin ìyìn fún ọ,nítorí ìwọ, Ọlọrun, ni odi mi,Ọlọrun tí ó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn mí.

Orin Dafidi 59