1. Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Ọlọrun mi;dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn tí ó gbógun tì mí.
2. Gbà mí lọ́wọ́ àwọn aṣebi,kí o sì yọ mí lọ́wọ́ àwọn apànìyàn.
3. Wò ó bí wọ́n ṣe lúgọ dè mí!OLUWA, àwọn jàǹdùkú eniyan kó ara wọn jọláti pa mí lára, láìṣẹ̀, láìrò.
4. Láìjẹ́ pé mo ṣẹ̀, wọ́n ń sáré kiri, wọ́n múra dè mí.Paradà, wá ràn mí lọ́wọ́, kí o sì rí i fúnra rẹ.
5. Ìwọ, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun,Ọlọrun Israẹli,jí gìrì, kí o jẹ gbogbo orílẹ̀-èdè níyà;má da ẹnìkan kan sí ninu àwọn tí ń fi ìwà ọ̀dàlẹ̀ pète ibi.
6. Ní alaalẹ́, wọn á pada wá,wọn á máa hu bí ajá, wọn a sì máa kiri ìlú.