Orin Dafidi 50:16-20 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Ṣugbọn Ọlọrun bi àwọn eniyan burúkú pé,“Ẹ̀tọ́ wo ni ẹ níláti máa ka àwọn òfin mi,tabi láti máa mú ẹnu ba ìlànà mi?

17. Nítorí ẹ kórìíra ẹ̀kọ́;ẹ sì ti ta àṣẹ mi nù.

18. Tí ẹ bá rí olè, ẹ̀yin pẹlu rẹ̀ a dọ̀rẹ́;ẹ sì ń bá àwọn panṣaga kẹ́gbẹ́.

19. “Ọ̀rọ̀ ibi dùn lẹ́nu yín pupọ;ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn sì yọ̀ létè yín.

20. Ẹ̀ ń jókòó sọ̀rọ̀ arakunrin yín níbi:ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ nípa ọmọ ìyá yín.

Orin Dafidi 50