Orin Dafidi 49:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ gbọ́, gbogbo orílẹ̀-èdè!Ẹ dẹtí sílẹ̀, gbogbo aráyé,

2. ati mẹ̀kúnnù àtọlọ́lá,àtolówó ati talaka!

3. Ẹnu mi yóo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n;àṣàrò ọkàn mi yóo sì jẹ́ ti òye.

4. N óo tẹ́tí sílẹ̀ sí òwe;n óo sì fi hapu túmọ̀ rẹ̀.

5. Kí ló dé tí n óo fi bẹ̀rù ní àkókò ìyọnu,nígbà tí iṣẹ́ ibi àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi bá yí mi ká,

6. àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn,tí wọ́n sì ń yangàn nítorí wọ́n ní ọrọ̀ pupọ?

7. Dájúdájú, kò sí ẹni tí ó le ra ara rẹ̀ pada,tabi tí ó lè san owó ìràpadà ẹ̀mí rẹ̀ fún Ọlọrun;

8. nítorí pé ẹ̀mí eniyan níye lórí pupọ.Kò sí iye tí eniyan ní tí ó le kájú rẹ̀,

9. tí eniyan lè máa fi wà láàyè títí lae,kí ó má fojú ba ikú.

10. Yóo rí i pé ikú a máa pa ọlọ́gbọ́n,òmùgọ̀ ati òpè a sì máa rọ̀run;wọn a sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.

11. Ibojì wọn ni ilé wọn títí lae,ibẹ̀ ni ibùgbé wọn títí ayérayé,wọn ìbáà tilẹ̀ ní ilẹ̀ ti ara wọn.

Orin Dafidi 49