1. Èrò rere kan ń gbé mi lọ́kàn,mò ń kọ orin mi fún ọbaahọ́n mi dàbí gègé akọ̀wé tó mọṣẹ́.
2. Ìwọ ni o dára jùlọ láàrin àwọn ọkunrin;ọ̀rọ̀ dùn lẹ́nu rẹ,nítorí náà Ọlọrun ti bukun ọ títí ayé.
3. Sán idà rẹ mọ́ ìdí, ìwọ alágbára,ninu ògo ati ọlá ńlá rẹ.
4. Máa gun ẹṣin ìṣẹ́gun lọ ninu ọlá ńlá rẹ,máa jà fún òtítọ́ ati ẹ̀tọ́,kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ fún ọ ní ìṣẹ́gun ńlá.