Orin Dafidi 44:9-14 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Sibẹ, o ti ta wá nù o sì ti rẹ̀ wá sílẹ̀,o ò sì bá àwọn ọmọ ogun wa jáde lọ sójú ogun mọ́.

10. O ti mú kí á sá fún àwọn ọ̀tá wa lójú ogun;àwọn tí ó kórìíra wa sì fi ẹrù wa ṣe ìkógun.

11. O ti ṣe wá bí aguntan lọ́wọ́ alápatà,o sì ti fọ́n wa káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè.

12. O ti ta àwọn eniyan rẹ lọ́pọ̀,o ò sì jẹ èrè kankan lórí wọn.

13. O ti sọ wá di ẹni ẹ̀gàn lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò wa;a di ẹni ẹ̀sín ati ẹni yẹ̀yẹ́ lọ́dọ̀ àwọn tí ó yí wa ká.

14. O sọ wá di ẹni àmúpòwe láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,ati ẹni yẹ̀yẹ́ láàrin gbogbo ayé.

Orin Dafidi 44