Orin Dafidi 44:24-26 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Kí ló dé tí o fi ń fi ojú pamọ́?Kí ló dé tí o fi gbàgbé ìpọ́njú ati ìnira wa?

25. Nítorí pé àwọn ọ̀tá ti tẹ̀ wá mọ́lẹ̀;àyà wa sì lẹ̀ mọ́lẹ̀ típẹ́típẹ́.

26. Gbéra nílẹ̀, kí o ràn wá lọ́wọ́!Gbà wá sílẹ̀ nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

Orin Dafidi 44