1. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń ro ti àwọn aláìní:OLUWA yóo gbà á ní ọjọ́ ìpọ́njú.
2. OLUWA yóo máa ṣọ́ ọ, yóo sì dá a sí.Yóo ní ayọ̀ ní ilẹ̀ náà;OLUWA kò ní fi í lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.
3. Nígbà tí ó bá wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn,OLUWA yóo fún un lókun;ní àkókò àìlera OLUWA yóo wo gbogbo àrùn rẹ̀ sàn.
4. Mo ní, “OLUWA, ṣàánú mi kí o sì wò mí sàn;mo ti ṣẹ̀ ọ́.”
5. Àwọn ọ̀tá mi ń ro ibi sí mi, wọ́n ń wí pé,“Nígbà wo ni yóo kú, tí orúkọ rẹ̀ yóo parẹ́?”
6. Tí ọ̀kan bá wá bẹ̀ mí wò,ọ̀rọ̀ tí kò lórí, tí kò nídìíni yóo máa sọ;bẹ́ẹ̀ ni ninu ọkàn rẹ̀, èrò ibi ni yóo máa gbà.Nígbà tí ó bá jáde,yóo máa rò mí kiri.