16. Nǹkan díẹ̀ tí olódodo nídára ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú.
17. Nítorí OLUWA yóo ṣẹ́ apá eniyan burúkú,ṣugbọn yóo gbé olódodo ró.
18. OLUWA a máa tọ́jú àwọn aláìlẹ́bi;ilẹ̀ ìní wọn yóo jẹ́ tiwọn títí lae.
19. Ojú kò ní tì wọ́n nígbà tí àjálù bá dé;bí ìyàn tilẹ̀ mú, wọn óo jẹ, wọn óo yó.
20. Ṣugbọn àwọn eniyan burúkú yóo ṣègbé;àwọn ọ̀tá OLUWA yóo pòórá bí ẹwà ewékowọn óo parẹ́ bí èéfín tí í parẹ́.
21. Bí eniyan burúkú bá yá owó, kò ní san;ṣugbọn ẹni rere ní ojú àánú, ó sì lawọ́.