4. Àní, bí mo tilẹ̀ ń rìn ninu òkùnkùn létí bèbè ikú,n kò ní bẹ̀rù ibi kankan;nítorí tí o wà pẹlu mi;ọ̀gọ rẹ ati ọ̀pá rẹ ń fi mí lọ́kàn balẹ̀.
5. O gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú mi,níṣojú àwọn ọ̀tá mi;o da òróró sí mi lórí;o sì bu ife mi kún ní àkúnwọ́sílẹ̀.
6. Dájúdájú, ire ati àánú yóo máa tẹ̀lé mi kiri,ní gbogbo ọjọ́ ayé mi;èmi óo sì máa gbé inú ilé OLUWA laelae.