Orin Dafidi 21:8-10 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ọwọ́ rẹ yóo tẹ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ;ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóo tẹ gbogbo àwọn tí ó kórìíra rẹ.

9. O óo jó wọn run bí iná ìléru, nígbà tí o bá yọ sí wọn.OLUWA yóo gbé wọn mì ninu ibinu rẹ̀;iná yóo sì jó wọn ní àjórun.

10. O óo pa àwọn ọmọ wọn run lórí ilẹ̀ ayé,o óo sì run ìran wọn láàrin àwọn eniyan.

Orin Dafidi 21