6. Láti apá kan ojú ọ̀run ni ó ti ń yọ wá,a máa yípo gbogbo ojú ọ̀run dé apá keji;kò sì sí ohun tí ó bọ́ lọ́wọ́ ooru rẹ̀.
7. Òfin OLUWA pé, a máa sọ ọkàn jí;àṣẹ OLUWA dájú, ó ń sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.
8. Ìlànà OLUWA tọ́, ó ń mú ọkàn yọ̀,àṣẹ OLUWA péye, a máa lani lójú.
9. Ìbẹ̀rù OLUWA pé, ó wà títí lae,ìdájọ́ OLUWA tọ́, òdodo ni gbogbo wọn.
10. Wọ́n wuni ju wúrà lọ,àní ju ojúlówó wúrà lọ;wọ́n sì dùn ju oyin,àní, wọ́n dùn ju oyin tí ń kán láti inú afárá lọ.
11. Pẹlupẹlu àwọn ni wọ́n ń ki èmi iranṣẹ rẹ, nílọ̀,èrè pupọ sì ń bẹ ninu pípa wọ́n mọ́.
12. Ṣugbọn ta ni lè mọ àṣìṣe ara rẹ̀?Wẹ̀ mí mọ́ ninu àṣìṣe àìmọ̀ mi.
13. Pa èmi iranṣẹ rẹ mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀-ọ́n-mọ̀-dá;má jẹ́ kí wọ́n jọba lórí mi.Nígbà náà ni ara mi yóo mọ́,n kò sì ní jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.