13. Dìde, OLUWA! Dojú kọ wọ́n; là wọ́n mọ́lẹ̀;fi idà rẹ gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú.
14. OLUWA, fi ọwọ́ ara rẹ gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan wọnyi;àwọn tí ìpín wọn jẹ́ ohun ti ayé yìí,fi ohun rere jíǹkí àwọn ẹni tí o pamọ́;jẹ́ kí àwọn ọmọ jẹ àjẹyó;sì jẹ́ kí àwọn ọmọ ọmọ wọn rí ogún wọn jẹ.
15. Ní tèmi, èmi óo rí ojú rẹ nítorí òdodo mi,ìrísí rẹ yóo sì tẹ́ mi lọ́rùn nígbà tí mo bá jí.