Orin Dafidi 145:18-21 BIBELI MIMỌ (BM)

18. OLUWA súnmọ́ gbogbo àwọn tí ń pè é,àní, àwọn tí ń pè é tọkàntọkàn.

19. Ó ń tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ lọ́rùn;ó ń gbọ́ igbe wọn, ó sì ń gbà wọ́n.

20. OLUWA dá gbogbo àwọn tí ó fẹ́ ẹ sí,ṣugbọn yóo pa gbogbo àwọn eniyan burúkú run.

21. Ẹnu mi yóo máa sọ̀rọ̀ ìyìn OLUWA;kí gbogbo ẹ̀dá máa yin orúkọ rẹ̀ lae ati laelae.

Orin Dafidi 145