6. Mo na ọwọ́ sí ọ fún ìrànlọ́wọ́;bí òùngbẹ omi í tií gbẹ ilẹ̀ gbígbẹ,bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi.
7. OLUWA, yára dá mi lóhùn!Ẹ̀mí mi ti fẹ́rẹ̀ pin!Má fara pamọ́ fún mi,kí n má baà dàbí àwọn tí ó ti lọ sinu isà òkú.
8. Jẹ́ kí n máa ranti ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ láràárọ̀,nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé.Kọ́ mi ní ọ̀nà tí n óo máa rìn,nítorí pé ìwọ ni mo gbójú sókè sí.
9. OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi;ìwọ ni mo sá di.
10. Kọ́ mi láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ,nítorí pé ìwọ ni Ọlọrun mi.Jẹ́ kí ẹ̀mí rere rẹ máa tọ́ mi ní ọ̀nà tí ó tọ́.
11. Nítorí ti orúkọ rẹ, OLUWA, dá mi sí;ninu òtítọ́ rẹ, yọ mí ninu ìpọ́njú.
12. Ninu ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, pa àwọn ọ̀tá mi,kí o sì pa gbogbo àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi run,nítorí pé iranṣẹ rẹ ni mí.