Orin Dafidi 143:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, gbọ́ adura mi;fetí sí ẹ̀bẹ̀ mi!Dá mi lóhùn ninu òtítọ́ ati òdodo rẹ.

2. Má dá èmi ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ lẹ́jọ́,nítorí pé kò sí ẹ̀dá alààyè tí ẹjọ́ rẹ̀ lè tọ́ níwájú rẹ.

3. Ọ̀tá ti lé mi bá,ó ti lù mí bolẹ̀;ó jù mí sinu òkùnkùn,bí ẹni tí ó ti kú tipẹ́tipẹ́.

Orin Dafidi 143