Orin Dafidi 142:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Mo ké pe OLUWA,mo gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ sókè sí i.

2. Mo tú ẹ̀dùn ọkàn mi palẹ̀ níwájú rẹ̀,mo sọ ìṣòro mi fún un.

3. Nígbà tí ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì,ó mọ ọ̀nà tí mo lè gbà.Wọ́n ti dẹ tàkúté sílẹ̀ fún miní ọ̀nà tí mò ń rìn.

Orin Dafidi 142