6. Bí ó ti wu OLUWA ni ó ń ṣelọ́run ati láyé,ninu òkun ati ninu ibú.
7. Òun ló gbá ìkùukùu jọ láti òpin ilẹ̀ ayé,ó fi mànàmáná fún òjò,ó sì mú afẹ́fẹ́ jáde láti inú ilé ìṣúra rẹ̀.
8. Òun ló pa àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti,ati teniyan ati tẹran ọ̀sìn.
9. Ẹni tí ó rán iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu sí ilẹ̀ Ijipti,ó rán sí Farao ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀.
10. Ẹni tí ó pa orílẹ̀-èdè pupọ run;ó pa àwọn ọba alágbára:
11. Sihoni ọba àwọn Amori,Ogu ọba Baṣani,ati gbogbo ọba ilẹ̀ Kenaani.
12. Ó pín ilẹ̀ wọn fún àwọn eniyan rẹ̀;ó pín in fún Israẹli bí ohun ìní wọn.