3. Bojúwò mí, kí o sì dá mi lóhùn, OLUWA, Ọlọrun mi.Tan ìmọ́lẹ̀ sí ojú mi, kí n má baà sun oorun ikú.
4. Kí ọ̀tá mi má baà wí pé, “Mo ti rẹ́yìn rẹ̀.”Kí àwọn tí ó kórìíra mi má baà yọ̀ bí mo bá ṣubú.
5. Ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;n óo máa yọ̀ nítorí pé o óo gbà mí.
6. N óo máa kọrin sí ọ, OLUWA,nítorí o ṣeun fún mi lọpọlọpọ.