1. OLUWA ni mo ké pè, nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú,ó sì dá mi lóhùn.
2. OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn èké,ati lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn.
3. Kí ni a óo fi san án fun yín?Kí ni a óo sì ṣe si yín, ẹ̀yin ẹlẹ́tàn?
4. Ọfà mímú ni a óo ta yín,a óo sì dáná sun yín.
5. Mo gbé! Nítorí pé mo dàbí àlejò tó wọ̀ ní Meṣeki,tí ń gbé ààrin àwọn àgọ́ Kedari.
6. Ó pẹ́ jù tí mo tí ń bá àwọn tí ó kórìíra alaafia gbé.