Orin Dafidi 12:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Gbani, OLUWA; nítorí àwọn olódodo kò sí mọ́;àwọn olóòótọ́ ti pòórá láàrin àwọn ọmọ eniyan.

2. Olukuluku ń purọ́ fún ẹnìkejì rẹ̀;ọ̀rọ̀ ìpọ́nni èké ati ẹ̀tàn ni wọ́n ń bá ara wọn sọ.

3. Kí OLUWA pa gbogbo àwọn tí ń fi èké pọ́nni run, ati àwọn tí ń fọ́nnu,

4. àwọn tí ń wí pé,“Ẹnu wa yìí ni a óo fi ṣẹgun,àwa la ni ẹnu wa; ta ni ó lè mú wa?”

Orin Dafidi 12