Orin Dafidi 119:118-127 BIBELI MIMỌ (BM)

118. O ti kọ gbogbo àwọn tí ó yapa kúrò ninu ìlànà rẹ sílẹ̀,nítorí pé asán ni gbogbo ẹ̀tàn wọn.

119. O ti pa àwọn eniyan burúkú tì, bí ìdàrọ́ irin,nítorí náà ni mo ṣe fẹ́ràn ìlànà rẹ.

120. Mo wárìrì nítorí pé mo bẹ̀rù rẹ,mo sì bẹ̀rù ìdájọ́ rẹ.

121. Mo ti ṣe ohun tí ó tọ́ tí ó sì yẹ,má fi mí sílẹ̀ fún àwọn tí wọn ń ni mí lára.

122. Ṣe ìlérí ìrànlọ́wọ́ fún ire èmi iranṣẹ rẹ,má sì jẹ́ kí àwọn onigbeeraga ni mí lára.

123. Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi,níbi tí mo tí ń retí ìgbàlà rẹ,ati ìmúṣẹ ìlérí òdodo rẹ.

124. Ṣe sí èmi iranṣẹ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

125. Iranṣẹ rẹ ni mí,fún mi lóye, kí n lè mọ ìlànà rẹ.

126. OLUWA, ó tó àkókò fún ọ láti ṣe nǹkankan,nítorí àwọn eniyan ń rú òfin rẹ.

127. Nítorí náà ni èmi ṣe fẹ́ràn òfin rẹju wúrà lọ; àní, ju ojúlówó wúrà.

Orin Dafidi 119