25. OLUWA, à ń bẹ̀ ọ́, gbà wá,OLUWA, à ń bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí á ṣe àṣeyege.
26. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ OLUWA,láti inú ilé rẹ ni a ti ń yìn ọ́, OLUWA.
27. OLUWA ni Ọlọrun, ó sì ti tan ìmọ́lẹ̀ sí wa.Pẹlu ẹ̀ka igi lọ́wọ́, ẹ bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ìwọ́de ẹbọ náà,títí dé ibi ìwo pẹpẹ.
28. Ìwọ ni Ọlọrun mi,n óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ.Ìwọ ni Ọlọrun mi,n óo máa gbé ọ ga.
29. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.