20. Èyí ni ẹnu ọ̀nà OLUWA;àwọn olódodo yóo gba ibẹ̀ wọlé.
21. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí pé o gbọ́ ohùn mi,o sì ti di olùgbàlà mi.
22. Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,ni ó di pataki igun ilé.
23. OLUWA ló ṣe èyí;ó sì jẹ́ ohun ìyanu lójú wa.
24. Òní ni ọjọ́ tí OLUWA dá,ẹ jẹ́ kí á máa yọ̀, kí inú wa sì máa dùn.
25. OLUWA, à ń bẹ̀ ọ́, gbà wá,OLUWA, à ń bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí á ṣe àṣeyege.
26. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ OLUWA,láti inú ilé rẹ ni a ti ń yìn ọ́, OLUWA.
27. OLUWA ni Ọlọrun, ó sì ti tan ìmọ́lẹ̀ sí wa.Pẹlu ẹ̀ka igi lọ́wọ́, ẹ bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ìwọ́de ẹbọ náà,títí dé ibi ìwo pẹpẹ.
28. Ìwọ ni Ọlọrun mi,n óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ.Ìwọ ni Ọlọrun mi,n óo máa gbé ọ ga.