Orin Dafidi 114:5-8 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Kí ló dé, tí o fi sá, ìwọ òkun?Kí ló ṣẹlẹ̀ tí o fi pada sẹ́yìn, ìwọ Jọdani?

6. Ẹ̀yin òkè ńlá, kí ló dé tí ẹ fi fò bí àgbò?Ẹ̀yin òkè kéékèèké, kí ló ṣẹlẹ̀ tí ẹ fi fò bí ọmọ aguntan?

7. Wárìrì níwájú OLUWA, ìwọ ilẹ̀,wárìrì níwájú Ọlọrun Jakọbu.

8. Ẹni tí ó sọ àpáta di adágún omi,tí ó sì sọ akọ òkúta di orísun omi.

Orin Dafidi 114