Orin Dafidi 110:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA wí fún oluwa mi, ọba, pé,“Jókòó sí apá ọ̀tún mi,títí tí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹdi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”

2. OLUWA yóo na ọ̀pá àṣẹ rẹ tí ó lágbára láti Sioni.O óo jọba láàrin àwọn ọ̀tá rẹ.

3. Àwọn eniyan rẹ yóo fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀,lọ́jọ́ tí o bá ń kó àwọn ọmọ ogun rẹ jọ lórí òkè mímọ́.Àwọn ọ̀dọ́ yóo jáde tọ̀ ọ́ wá bí ìrì òwúrọ̀.

4. OLUWA ti búra, kò sì ní yí ọkàn rẹ̀ pada, pé,“Alufaa ni ọ́ títí lae,nípasẹ̀ Mẹlikisẹdẹki.”

Orin Dafidi 110