Orin Dafidi 107:38-41 BIBELI MIMỌ (BM)

38. Ó bukun wọn, ó mú kí wọn bí sí i lọpọlọpọ,kò sì jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọ́n dínkù.

39. Nígbà tí wọ́n dínkù, tí a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,nípa ìnira, ìpọ́njú, ati ìṣòro,

40. ó da ẹ̀gàn lu àwọn ìjòyè,ó sì mú kí wọn máa rìn kiri ní aṣálẹ̀,níbi tí kò sí ọ̀nà.

41. Ṣugbọn ó yọ aláìní kúrò ninu ìpọ́njú,ó sì mú kí ìdílé wọn pọ̀ sí i bí agbo ẹran.

Orin Dafidi 107