Orin Dafidi 107:37-40 BIBELI MIMỌ (BM)

37. Wọ́n dáko, wọ́n gbin àjàrà,wọ́n sì kórè lọpọlọpọ.

38. Ó bukun wọn, ó mú kí wọn bí sí i lọpọlọpọ,kò sì jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọ́n dínkù.

39. Nígbà tí wọ́n dínkù, tí a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,nípa ìnira, ìpọ́njú, ati ìṣòro,

40. ó da ẹ̀gàn lu àwọn ìjòyè,ó sì mú kí wọn máa rìn kiri ní aṣálẹ̀,níbi tí kò sí ọ̀nà.

Orin Dafidi 107