Orin Dafidi 106:9-28 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ó bá òkun pupa wí, òkun pupa gbẹ,ó sì mú wọn la ibú já bí ẹni rìn ninu aṣálẹ̀.

10. Ó gbà wọ́n là lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wọn,ó sì kó wọn yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.

11. Omi bo àwọn ọ̀tá wọn,ẹyọ ẹnìkan kò sì là.

12. Nígbà náà ni wọ́n tó gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́,wọ́n sì kọrin yìn ín.

13. Kò pẹ́ tí wọ́n tún fi gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀,wọn kò sì dúró gba ìmọ̀ràn rẹ̀.

14. Wọ́n ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ní aṣálẹ̀,wọ́n sì dán Ọlọrun wò.

15. Ó fún wọn ní ohun tí wọ́n bèèrè,ṣugbọn ó fi àìsàn ajẹnirun ṣe wọ́n.

16. Nígbà tí wọ́n ṣe ìlara sí Mose ninu ibùdó,ati sí Aaroni, ẹni mímọ́ OLÚWA.

17. Ilẹ̀ yanu, ó gbé Datani mì,ó sì bo Abiramu ati àwọn tí ó tẹ̀lé e mọ́lẹ̀.

18. Iná sọ láàrin wọn,ó sì jó àwọn eniyan burúkú náà run.

19. Wọ́n yá ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù ní Horebu,wọ́n sì bọ ère tí wọ́n dà.

20. Wọ́n gbé ògo Ọlọrunfún ère mààlúù tí ń jẹ koríko.

21. Wọ́n gbàgbé Ọlọrun, Olùgbàlà wọn,tí ó ṣe iṣẹ́ ribiribi ní Ijipti,

22. ó ṣe, iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu,ati ohun ẹ̀rù lẹ́bàá òkun pupa.

23. Nítorí náà ni ó ṣe wí pé òun yóo pa wọ́n run,bí kì í bá ṣe ti Mose, àyànfẹ́ rẹ̀,tí ó dúró níwájú rẹ̀, tí ó sì ṣìpẹ̀,láti yí ibinu OLUWA pada, kí ó má baà pa wọ́n run.

24. Wọn kò bìkítà fún ilẹ̀ dáradára náà,wọn kò sì ní igbagbọ ninu ọ̀rọ̀ OLUWA.

25. Wọ́n ń kùn ninu àgọ́ wọn,wọn kò sì fetí sí ohùn OLUWA.

26. Nítorí náà, ó gbé ọwọ́ sókè, ó búra fún wọnpé òun yóo jẹ́ kí wọ́n kú sí aṣálẹ̀,

27. ati pé òun yóo fọ́n àwọn ìran wọn káàkiriàwọn orílẹ̀-èdè.

28. Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali ti Peori,wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí wọ́n rú sí òkú.

Orin Dafidi 106