6. A ti ṣẹ̀, àtàwa, àtàwọn baba wa,a ti ṣe àìdára, a sì ti hùwà burúkú.
7. Nígbà tí àwọn baba ńlá wa wà ní Ijipti,wọn kò náání iṣẹ́ ìyanu rẹ,wọn kò sì ranti bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ti pọ̀ tó.Ṣugbọn wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo lẹ́bàá òkun pupa.
8. Sibẹsibẹ, ó gbà wọ́n là, nítorí orúkọ rẹ̀;kí ó lè fi títóbi agbára rẹ̀ hàn.
9. Ó bá òkun pupa wí, òkun pupa gbẹ,ó sì mú wọn la ibú já bí ẹni rìn ninu aṣálẹ̀.
10. Ó gbà wọ́n là lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wọn,ó sì kó wọn yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.