5. Ẹ ranti iṣẹ́ ribiribi tí ó ti ṣe,ẹ ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ati ìdájọ́ rẹ̀.
6. Ẹ̀yin ọmọ Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀,ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.
7. OLUWA ni Ọlọrun wa,ìdájọ́ rẹ̀ kárí gbogbo ayé.
8. Títí lae ni ó ń ranti majẹmu rẹ̀,ó ranti àṣẹ tí ó pa fún ẹgbẹẹgbẹrun ìran,
9. majẹmu tí ó bá Abrahamu dá,ìlérí tí ó fi ìbúra ṣe fún Isaaki,
10. tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí òfin,àní fún Israẹli gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ayérayé,
11. ó ní: “Ẹ̀yin ni n óo fi ilẹ̀ Kenaani fún,yóo jẹ́ ìpín yín tí ẹ óo jogún.”
12. Nígbà tí wọ́n kéré ní iye,tí wọn kò tíì pọ̀ rárá, tí wọn sì jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ náà,
13. tí wọn ń káàkiri láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè,láti ìjọba kan dé òmíràn,
14. kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ni wọ́n lára,ó bá àwọn ọba wí nítorí wọn.
15. Ó ní, “Ẹ kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ẹni àmìòróró mi,ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe àwọn wolii mi níbi.”
16. Nígbà kan, ó mú kí ìyàn jà ní ilẹ̀ náà:ó ṣẹ́ ọ̀pá oúnjẹ mọ́ wọn lẹ́nu.
17. Ṣugbọn ó kọ́ rán ọkunrin kan ṣáájú wọn,Josẹfu, ẹni tí a tà lẹ́rú.
18. Wọ́n so ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ mọ́ ọn lẹ́sẹ̀,wọ́n ti ọrùn rẹ̀ bọ irin,
19. títí ìgbà tí ohun tí ó sọ fi ṣẹ,tí OLUWA sì jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
20. Ọba ranṣẹ pé kí wọ́n tú u sílẹ̀,aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè sì dá a sílẹ̀.
21. Ó fi jẹ aláṣẹ ilé rẹ̀,ati alákòóso gbogbo nǹkan ìní rẹ̀;
22. láti máa ṣe olórí àwọn ìjòyè rẹ̀,kí ó sì máa kọ́ àwọn àgbà ìlú ní ìmọ̀.