Orin Dafidi 105:24-36 BIBELI MIMỌ (BM)

24. OLUWA mú kí àwọn eniyan rẹ̀ pọ̀ sí i,ó sì mú kí wọ́n lágbára ju àwọn ọ̀tá wọn lọ.

25. Ó yí àwọn ará Ijipti lọ́kàn pada,tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi kórìíra àwọn eniyan rẹ̀,tí wọ́n sì hùwà àrékérekè sí àwọn iranṣẹ rẹ̀.

26. Ó rán Mose, iranṣẹ rẹ̀,ati Aaroni, ẹni tí ó yàn.

27. Wọ́n ṣe iṣẹ́ àmì rẹ̀ ní ilẹ̀ náà,wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ní ilẹ̀ Hamu,

28. Ọlọrun rán òkùnkùn, ilẹ̀ sì ṣú,ṣugbọn wọ́n ṣe oríkunkun sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

29. Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀,ó sì mú kí ẹja wọn kú.

30. Ọ̀pọ̀lọ́ ń tú jáde ní ilẹ̀ wọn,títí kan ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn.

31. Ọlọrun sọ̀rọ̀, eṣinṣin sì rọ́ dé,iná aṣọ sì bo gbogbo ilẹ̀ wọn.

32. Ó rọ̀jò yìnyín lé wọn lórí,mànàmáná sì ń kọ káàkiri ilẹ̀ wọn.

33. Ó kọlu àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn,ó sì wó àwọn igi ilẹ̀ wọn.

34. Ó sọ̀rọ̀, àwọn eṣú sì rọ́ dé,ati àwọn tata tí kò lóǹkà;

35. wọ́n jẹ gbogbo ewé tí ó wà ní ilẹ̀ wọn,ati gbogbo èso ilẹ̀ náà.

36. Ó kọlu gbogbo àkọ́bí ilẹ̀ wọn,àní, gbogbo àrẹ̀mọ ilẹ̀ wọn.

Orin Dafidi 105