Orin Dafidi 105:23-41 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Lẹ́yìn náà, Israẹli dé sí Ijipti,Jakọbu ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Hamu.

24. OLUWA mú kí àwọn eniyan rẹ̀ pọ̀ sí i,ó sì mú kí wọ́n lágbára ju àwọn ọ̀tá wọn lọ.

25. Ó yí àwọn ará Ijipti lọ́kàn pada,tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi kórìíra àwọn eniyan rẹ̀,tí wọ́n sì hùwà àrékérekè sí àwọn iranṣẹ rẹ̀.

26. Ó rán Mose, iranṣẹ rẹ̀,ati Aaroni, ẹni tí ó yàn.

27. Wọ́n ṣe iṣẹ́ àmì rẹ̀ ní ilẹ̀ náà,wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ní ilẹ̀ Hamu,

28. Ọlọrun rán òkùnkùn, ilẹ̀ sì ṣú,ṣugbọn wọ́n ṣe oríkunkun sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

29. Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀,ó sì mú kí ẹja wọn kú.

30. Ọ̀pọ̀lọ́ ń tú jáde ní ilẹ̀ wọn,títí kan ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn.

31. Ọlọrun sọ̀rọ̀, eṣinṣin sì rọ́ dé,iná aṣọ sì bo gbogbo ilẹ̀ wọn.

32. Ó rọ̀jò yìnyín lé wọn lórí,mànàmáná sì ń kọ káàkiri ilẹ̀ wọn.

33. Ó kọlu àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn,ó sì wó àwọn igi ilẹ̀ wọn.

34. Ó sọ̀rọ̀, àwọn eṣú sì rọ́ dé,ati àwọn tata tí kò lóǹkà;

35. wọ́n jẹ gbogbo ewé tí ó wà ní ilẹ̀ wọn,ati gbogbo èso ilẹ̀ náà.

36. Ó kọlu gbogbo àkọ́bí ilẹ̀ wọn,àní, gbogbo àrẹ̀mọ ilẹ̀ wọn.

37. Lẹ́yìn náà, ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde,tàwọn ti fadaka ati wúrà,kò sì sí ẹnikẹ́ni ninu ẹ̀yà kankan tí ó ṣe àìlera.

38. Inú àwọn ará Ijipti dùn nígbà tí wọ́n jáde,nítorí ẹ̀rù àwọn ọmọ Israẹli ń bà wọ́n.

39. OLUWA ta ìkùukùu bò wọ́n,ó sì pèsè iná láti tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn lóru.

40. Wọ́n bèèrè ẹran, ó fún wọn ní àparò,ó sì pèsè oúnjẹ àjẹtẹ́rùn fún wọn láti ọ̀run.

41. Ó la àpáta, omi tú jáde,ó sì ṣàn ninu aṣálẹ̀ bí odò.

Orin Dafidi 105