31. Mose ati Eleasari sì ṣe bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún wọn.
32. Ìkógun tí ó kù ninu àwọn tí àwọn ọmọ ogun kó bọ̀ láti ojú ogun jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹrinlelọgbọn ó dín ẹgbẹẹdọgbọn (675,000) aguntan.
33. Ẹgbaa mẹrindinlogoji (72,000) mààlúù.
34. Ọ̀kẹ́ mẹta ó lé ẹgbẹrun (61,000) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
35. Àwọn ọdọmọbinrin tí kò tíì mọ ọkunrin jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlogun (32,000).
36. Ìdajì rẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ ogun jẹ́ ẹgbaa mejidinlaadọsan-an ó lé ẹẹdẹgbẹjọ (337,500) aguntan.
37. Ìpín ti OLUWA ninu rẹ̀ jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó dín mẹẹdọgbọn (675).
38. Mààlúù jẹ́ ẹgbaa mejidinlogun (36,000), ìpín ti OLUWA ninu rẹ̀ jẹ́ mejilelaadọrin.
39. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ jẹ́ ẹgbaa mẹẹdogun ó lé ẹẹdẹgbẹta (30,500), ìpín ti OLUWA ninu rẹ̀ jẹ́ mọkanlelọgọta.
40. Àwọn eniyan sì jẹ́ ẹgbaajọ (16,000), ìpín ti OLUWA jẹ́ mejilelọgbọn.