8. Sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé nígbà tí ẹnìkan bá kú láìní ọmọkunrin, àwọn ọmọbinrin rẹ̀ yóo jogún ilẹ̀ ìní rẹ̀.
9. Bí kò bá sì ní ọmọbinrin, ilẹ̀ ìní rẹ̀ yóo jẹ́ ti àwọn arakunrin rẹ̀.
10. Bí kò bá ní arakunrin, kí ẹ fi ilẹ̀ ìní rẹ̀ fún àwọn arakunrin baba rẹ̀.
11. Bí baba rẹ̀ kò bá ní arakunrin, ẹ fi ilẹ̀ ìní rẹ̀ fún ìbátan rẹ̀ tí ó bá súnmọ́ ọn jùlọ ninu ìdílé rẹ̀. Ìbátan rẹ̀ yìí ni yóo jogún rẹ̀. Èyí yóo máa jẹ́ ìlànà fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.”
12. OLUWA sọ fún Mose pé, “Gun orí òkè Abarimu yìí lọ, kí o sì wo ilẹ̀ tí n óo fún àwọn ọmọ Israẹli.
13. Lẹ́yìn náà tí o bá ti wò ó tán, ìwọ náà yóo kú gẹ́gẹ́ bíi Aaroni arakunrin rẹ,