Nọmba 27:12-20 BIBELI MIMỌ (BM)

12. OLUWA sọ fún Mose pé, “Gun orí òkè Abarimu yìí lọ, kí o sì wo ilẹ̀ tí n óo fún àwọn ọmọ Israẹli.

13. Lẹ́yìn náà tí o bá ti wò ó tán, ìwọ náà yóo kú gẹ́gẹ́ bíi Aaroni arakunrin rẹ,

14. nítorí o ṣàìgbọràn sí àṣẹ mi ninu aṣálẹ̀ Sini. Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń kùn sí mi ní Meriba, ẹ kọ̀ láti fi títóbi agbára mi hàn níwájú àwọn eniyan náà.” (Meriba ni wọ́n ń pe àwọn omi tí ó wà ní Kadeṣi ní aṣálẹ̀ Sini).

15. Mose bá gbadura báyìí pé,

16. “OLUWA Ọlọrun, ìwọ ni orísun ìyè gbogbo nǹkan alààyè. Èmi bẹ̀ ọ́, yan ẹnìkan tí yóo máa ṣáájú àwọn eniyan wọnyi:

17. ẹni tí ó lè máa ṣáájú wọn lójú ogun, kí àwọn eniyan rẹ má baà wà bí aguntan tí kò ní olùṣọ́.”

18. OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Mú Joṣua ọmọ Nuni, ẹni tí Ẹ̀mí èmi OLUWA wà ninu rẹ̀, gbé ọwọ́ rẹ lé e lórí,

19. kí o mú un wá siwaju Eleasari alufaa ati gbogbo àwọn eniyan, kí o sì fún un ní àṣẹ lójú wọn.

20. Fún un ninu iṣẹ́ rẹ, kí àwọn ọmọ Israẹli lè tẹríba fún un.

Nọmba 27