10. Ta ló lè ka àwọn ọmọ Jakọbu tí ó pọ̀ bí iyanrìn?Tabi kí ó ka idamẹrin àwọn ọmọ Israẹli?Jẹ́ kí n kú ikú olódodo,kí ìgbẹ̀yìn mi sì dàbí tirẹ̀.”
11. Nígbà náà ni Balaki sọ fún Balaamu pé, “Kí ni ò ń ṣe sí mi yìí? Mo mú ọ wá láti ṣépè lé àwọn ọ̀tá mi, ṣugbọn ò ń súre fún wọn.”
12. Ó sì dáhùn pé, “Ohun tí OLUWA bá sọ fún mi ni mo gbọdọ̀ sọ.”
13. Balaki sọ fún Balaamu pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn. Apákan wọn ni o óo rí, o kò ní rí gbogbo wọn, níbẹ̀ ni o óo ti bá mi ṣépè lé wọn.”
14. Ó bá mú un lọ sórí òkè Pisiga ní pápá Sofimu. Ó tún tẹ́ pẹpẹ meje, ó sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.
15. Balaamu sọ fún Balaki pé, “Dúró ti ẹbọ sísun rẹ, n óo lọ pàdé OLUWA lọ́hùn-ún.”
16. OLUWA rán Balaamu pada sí Balaki pẹlu ohun tí yóo sọ.
17. Nígbà tí ó pada dé ó bá Balaki ati àwọn àgbààgbà Moabu, wọ́n dúró ti ẹbọ sísun náà, Balaki sì bèèrè ohun tí OLUWA sọ lọ́wọ́ rẹ̀.
18. Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní:“Balaki, dìde, wá gbọ́,fetí sí mi, ọmọ Sipori;