Nọmba 14:20-31 BIBELI MIMỌ (BM)

20. OLUWA dáhùn pé, “Mo ti dáríjì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bẹ̀ rẹ.

21. Ṣugbọn nítòótọ́, níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè, tí ògo mi sì kún ayé,

22. àwọn eniyan wọnyi, tí wọ́n ti rí ògo mi ati àwọn iṣẹ́ ìyanu tí mo ṣe ní Ijipti ati ninu aṣálẹ̀, ṣugbọn tí wọ́n ti dán mi wò nígbà mẹ́wàá, tí wọ́n sì ṣàìgbọràn sí mi,

23. ẹnikẹ́ni ninu wọn kò ní dé ilẹ̀ tí mo ti ṣe ìlérí fún àwọn baba wọn. Ẹyọ kan ninu àwọn tí wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀ wọnyi kò ní débẹ̀.

24. Ṣugbọn nítorí pé iranṣẹ mi, Kalebu, ní ẹ̀mí tí ó yàtọ̀, ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí mi, n óo mú un dé ilẹ̀ tí ó lọ wò, ilẹ̀ náà yóo sì jẹ́ ti àwọn ọmọ rẹ̀.

25. Nítorí pé àwọn Amaleki ati ará Kenaani ń gbé àfonífojì, ní ọ̀la, ẹ gbéra, kí ẹ gba ọ̀nà Òkun Pupa lọ sinu aṣálẹ̀.”

26. OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé,

27. “Yóo ti pẹ́ tó tí àwọn eniyan burúkú wọnyi yóo fi máa kùn sí mi? Mo ti gbọ́ gbogbo kíkùn tí wọn ń kùn sí mi.

28. Nisinsinyii, sọ fún wọn pé, ‘Bí mo tì wà láàyè, n óo ṣe yín gẹ́gẹ́ bí ẹ ti wí.

29. Ẹ óo kú ninu aṣálẹ̀ yìí; gbogbo yín; ohun tí ó ṣẹ̀ láti ẹni ogún ọdún lọ sókè, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kùn sí mi.

30. Ẹnikẹ́ni ninu yín kò ní wọ ilẹ̀ tí mo ti búra pé yóo jẹ́ ibùgbé yín, àfi Kalebu ọmọ Jefune ati Joṣua, ọmọ Nuni.

31. Ṣugbọn àwọn ọmọ yín tí ẹ sọ pé ogun yóo kó, ni n óo mú dé ilẹ̀ náà; ilẹ̀ tí ẹ kọ̀ sílẹ̀ yóo sì jẹ́ tiwọn.

Nọmba 14