25. OLUWA sọ̀kalẹ̀ ninu ìkùukùu láti bá Mose sọ̀rọ̀. Ó sì mú lára ẹ̀mí tí ó wà lára Mose, ó fi sára àwọn aadọrin olórí náà. Bí ẹ̀mí náà ti bà lé wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀, ṣugbọn wọn kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ mọ́ lẹ́yìn ọjọ́ náà.
26. Meji ninu àwọn olórí náà: Elidadi ati Medadi, kò bá wọn lọ, wọ́n dúró sinu àgọ́ wọn. Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé wọn, wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀.
27. Ọmọkunrin kan sáré wá sọ fún Mose pé Elidadi ati Medadi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀.
28. Nígbà náà ni Joṣua, ọmọ Nuni, iranṣẹ Mose, ọ̀kan ninu àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ wí fún Mose pé, “Pa wọ́n lẹ́nu mọ́.”
29. Mose dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń jowú nítorí mi? Inú mi ìbá dùn bí OLUWA bá lè fún gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ ní ẹ̀mí rẹ̀ kí wọ́n sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀.”
30. Lẹ́yìn náà Mose ati àwọn aadọrin olórí náà pada sí ibùdó.