15. Bí ó bá jẹ́ pé bí o óo ti ṣe mí nìyí, mo bẹ̀ ọ́, kúkú pa mí bí inú rẹ bá yọ́ sí mi, kí n má baà kan àbùkù.”
16. OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Yan aadọrin ninu àwọn àgbààgbà Israẹli, àwọn tí àwọn ọmọ Israẹli mọ̀ ní olórí, kí o sì mú wọn wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Kí wọ́n dúró pẹlu rẹ níbẹ̀.
17. N óo wá bá ọ sọ̀rọ̀ níbẹ̀. N óo mú lára ẹ̀mí tí ó wà lára rẹ, n óo fi sí wọn lára; kí wọn lè máa ràn ọ́ lọ́wọ́, láti gbé ẹrù àwọn eniyan náà, kí ìwọ nìkan má baà máa ṣe iṣẹ́ náà.
18. Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, ẹ óo jẹ ẹran lọ́la. OLUWA ti gbọ́ ẹkún ati ìráhùn yín pé, ‘Ta ni yóo fún wa ní ẹran jẹ, ó sàn fún wa jù báyìí lọ ní ilẹ̀ Ijipti.’ Nítorí náà OLUWA yóo fun yín ní ẹran.
19. Kì í ṣe èyí tí ẹ óo jẹ ní ọjọ́ kan, tabi ọjọ́ meji, tabi ọjọ́ marun-un, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe fún ọjọ́ mẹ́wàá, tabi fún ogúnjọ́.
20. Ṣugbọn odidi oṣù kan ni ẹ óo fi jẹ ẹ́, títí tí yóo fi fẹ́rẹ̀ hù lórí yín, tí yóo sì sú yín, nítorí pé ẹ ti kọ OLUWA tí ó wà láàrin yín sílẹ̀, ẹ sì ti ráhùn níwájú rẹ̀ pé: ‘Kí ló dé tí a fi kúrò ní Ijipti.’ ”
21. Mose sì sọ fún OLUWA pé, “Àwọn tí wọn tó ogun jà nìkan ninu àwọn eniyan tí mò ń ṣe àkóso wọn yìí jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) o sì wí pé o óo fún wọn ní ẹran jẹ fún oṣù kan.
22. Ṣé a lè rí mààlúù tabi aguntan tí yóo tó láti pa fún wọn? Ǹjẹ́ gbogbo ẹja tí ó wà ninu òkun tó fún wọn bí?”
23. OLUWA dá Mose lóhùn, ó ní, “Ǹjẹ́ nǹkankan wà tí ó ṣòro fún èmi OLUWA láti ṣe bí? O óo rí i bóyá ohun tí mo sọ fún ọ yóo ṣẹ, tabi kò ní ṣẹ.”
24. Mose jáde, ó lọ sọ ohun tí OLUWA sọ fún àwọn ọmọ Israẹli; ó sì mú àwọn aadọrin olórí náà wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.
25. OLUWA sọ̀kalẹ̀ ninu ìkùukùu láti bá Mose sọ̀rọ̀. Ó sì mú lára ẹ̀mí tí ó wà lára Mose, ó fi sára àwọn aadọrin olórí náà. Bí ẹ̀mí náà ti bà lé wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀, ṣugbọn wọn kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ mọ́ lẹ́yìn ọjọ́ náà.
26. Meji ninu àwọn olórí náà: Elidadi ati Medadi, kò bá wọn lọ, wọ́n dúró sinu àgọ́ wọn. Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé wọn, wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀.