Nehemaya 13:27-31 BIBELI MIMỌ (BM)

27. Ṣé a óo wá tẹ̀lé ìṣìnà yín, kí á sì máa ṣe irú nǹkan burúkú yìí, kí á sì máa fẹ́ àwọn obinrin àjèjì tí ó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọrun wa?”

28. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọkunrin Jehoiada, ọmọ Eliaṣibu olórí alufaa, fẹ́ ọmọ Sanbalati ará Horoni kan, nítorí náà mo lé e kúrò lọ́dọ̀ mi.

29. Ranti, Ọlọrun mi, nítorí pé wọ́n rú òfin àwọn alufaa, wọn kò sì mú ẹ̀jẹ́ àwọn alufaa ati ti àwọn ọmọ Lefi ṣẹ.

30. Nítorí náà mo wẹ̀ wọ́n mọ́ ninu gbogbo nǹkan àjèjì, mo sì fi ìdí iṣẹ́ wọn múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alufaa ati ọmọ Lefi. Olukuluku sì ní iṣẹ́ tí ó ń ṣe,

31. mo pèsè igi ìrúbọ, ní àkókò tí ó yẹ ati àwọn èso àkọ́so.Ranti mi sí rere, Ọlọrun mi.

Nehemaya 13